Tolulope Emmanuel, Osogbo
Enjinia Abioye Emmanuel to n mojuto ileese omi to wa nilu Ede, Ede Water Works ti ni titi lae lawon eeyan ipinle Osun yoo maa gboriyin fun ijoba Gomina Aregbesola lori igbese to gbe nipa ipese omi to mo gaara.
Abioye ni ninu itan ipinle Osun, ijoba Aregbesola nikan lo mo isepataki ipese omi to see mu fawon araalu eleyii to ni o wa lara idi ti awon eeyan ko fi gburo arun to n ti ara omi jade nipinle Osun.
O soro yii lasiko to n mu awon oniroyin kaakiri ileese naa lara awon eto ti egbe kan ti ko rogboku lejoba, Oranmiyan Group gbe kale lati sami ayeye odun keje isejoba Gomina Aregbesola nipinle Osun.
O ni ohun to n fa aito omi ati ifarahan oniruuru awon arun teeyan maa n ko lara omi ti ko dara ni aisi irinse to peye lorisun ti omi n gba jade ati aisi amojuto fawon irinse to wa nibe.
O ni awon nnkan yii nijoba Aregbesola koko mojuto eleyii to ni o ti mu ki isowosise orisun omi naa wa nipele ida aadorin ninu ogorun bayii yato si ipele ida meedogbon ninu ogorun to wa tele.
Abioye ni ero amunawa eyokansoso lo wa nileese naa ko too di pe Gomina Aregbesola de sugbon to ti di marun bayii, bee nijoba yii tun ra ero ifami (pumping machine) atawon oniruuru irinse eleyii to ni o n mu kileese naa maa fa omi ni gbogbo wakati merinlelogun to wa ninu ojo.
O ni ijoba ibile merinla ni Ede Water Works n fa omi fun bayii nipinle Osun, idi niyii to fi ro awon agbegbe naa lati tete maa fi to ileese won leti ti opa omi ba be nibikibi fun atunse ni kiakia.
Bakan naa ni enjinia yii ro won lati maa san owo omi won deede lati le je koriya fun akitiyan ijoba.
Ninu oro tie, adari iko to n lo kaakiri ohun, Comreedi Rasheed Raji-Ropo sapejuwe igbese Gomina Aregbesola lori ipese omi to mo gaara fawon araalu gege bii opakutele si igbe aye irorun.
Raji ni owo ribiribi tijoba na lati le pese omi to mo gaara yii ye leyii ti gbogbo awon araalu gbodo gboriyin fun nitori ko see se lati maa soro ilera pipe lai soro omi to mo gaara.
O waa ki gomina ku oriire ayeye odun keje to ti dori aleefa, bakan naa lo ro awon araalu lati mu sisan owo ori won lasiko nibaada kijoba le maa tesiwaju ninu awon ise akanse to n se.



No comments:
Post a Comment