IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 25 November 2017

Mo ti mo tele pe Atiku maa kuro ninu egbe APC - el-Rufai


Gomina ipinle Kaduna, Nasir el-Rufai ni ko ya oun lenu bi igbakeji aare orileede yii tele, Alhaji Atiku Abubakar se digba-dagbon re kuro ninu egbe oselu APC.

el-Rufai ni o pe ti oun ti mo pe Atiku yoo gbe igbese naa nitori gbogbo erongba re ninu egbe oselu to ba lo ni pe ki won fi tikeeti aare le e lowo, ko si nii besubegba lati sa kuro nibi to ba ti ro pe eleyii le ma ri bee.

O ni alakoka oloselu ni Atiku latibere aye e, eyi to si tun se yii fihan pe kii se enikeni lo le e bikose erongba re lati di aare orileede yii.

el-Rufai so fawon oniroyin pe loooto loun ko iwe kan si Aare Buhari lodun to koja pe bi won se n se si Alhaji Atiku Abubakar pelu Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ku die kaa to sugbon iyen ko so pe kikuro ninu egbe ni ona abayo.

O waa ro awon omo egbe to ku lati se araa won losusu owo.

No comments:

Post a Comment