Tolulope Emmanuel, Osogbo
Gbogbo awon eeyan ipinle Osun ni won ti so pe asa dida abe fomobinrin ti di afiseyin teegun n fi aso bayii, ati pe enikeni to ba tun hu iru iwa bee yoo kabamo e.
Nibi ipade apero kan eleyii to waye nilu Apomu nijoba ibile Isokan ni awon ori-ade ti won to ogoji pelu awon lookolooko ti oro kan nipinle Osun ti so pe tojutiye taparo fi n riran lawon fi oro igbogunti abe dida fawon obinrin se nilu tawon n dari.
Asa naa, eleyii ti won ni o n se akoba nla fawon omobinrin lojo iwaju lo ye ki toloritelemu gbogun ti, ki ogun re si se patapata.
Nibi eto naa, eleyii ti ajo kan ti ko rogboku le ijoba, Action Health Incorporated (AHI) pelu ibasepo UNFPA sagbateru re pelu ijoba ipinle Osun ni gbogbo awon ti won wa nibe ti n so ipa ti dida abe fawon omobinrin nko eleyii to to lati gbogunti.
Alakoso eto fun ajo AHI, Ms Tina Igbinedion so pe aseyori nla nijoba Gimina Aregbesola tipinle Osun ti se nipase igbogunti abe dida fobinrin beeyan ba wo ohun to n sele tele.
Obinrin yii waa ni ajo AHI ko nii kaare nipa ipolongo re lori igbogunti abe dida fawon omobinrin nipinle Osun.

No comments:
Post a Comment