IROYIN YAJOYAJO

Friday, 8 December 2017

Dereba to wa moto epo to paayan mokanla n'Ileefe lojosi ti foju bale ejo


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Adajo majistreeti kan nlu Ileefe, Olalekan Ijiyode ti gba beeli okunrin dereba tanka epo kan to lasidenti nilu Ileefe laipe yii pelu milioonu kan naira ati oniduro meji ni iye kannaa.

Abibu Odeyemi lo n jejo esun merin otooto to nii se pelu wiwa oko niwakuwa, ipaniyan nipase asidenti (manslaughter), biba moto je ati mimu awon ero inu oko farapa.

Ojo ketalelogun osu keje odun yii ni tanka epo tileese IVECO ti Abibu wa ni asidenti, leyin naa lo gbina loju ese eleyii to mu kawon eeyan mokanla je Olorun nipe.

Agbejoro funleese olopa lori oro naa, Sajenti Sunday Osanyintuyi salaye funle ejo pe isele naa, eleyii to sele ni nnkan aago mokanla aaro ojo naa lagbegbe Energy Filling Station, Ibadan Express Road nilu Ileefe lo so opolopo sinu ibanuje ayeraye.

Osanyintuyi ni moto tanka to ni nomba YNF 328 XA ni Abibu wa niwakuwa lojo naa eleyii to yori si ikuu Ogbeni Najeem Akanni atawon ero mewa miin.

O ni bakan naa ni opolopo awon eeyan, ninu eyi ti a ti ri Isiaka Salawu farapa yannayanna.

Osanyintuyi ni iwa ti Abibu hu naa je eyi to lodi si ofin iwako ojuupopo ti odun 2002. 

Abibu ni oun ko jebi awon esun naa, bee ni agbejoro re, Ogbeni Adeboye J.A. ro ile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo lona irorun pelu ileri pe ko nii salo fun igbejo.

 Majistreeti Olalekan Ijiyode gba beeli olujejo pelu milioonu kan naira ati oniduro meji ni iye kannaa.

O ni okan lara awon oniduro naa gbodo wa ni ipele owo osu kefa lenu ise ijoba, o si gbodo maa gbe lagbegbe kootu pelu adiresi tawon olopa mo.

Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kokandinlogun osu kejila odun yii.

No comments:

Post a Comment