Tolulope Emmanuel, Osogbo
Alaga egbe oselu APC nipinle Osun, Omooba Gboyega Famoodun ti ni ko nilo ki enikeni so fun okan lara awon asaaju egbe naa, Fatai Diekola pe asiko re ti to lati fi egbe naa sile nitori ko huwa bii agba tawon eeyan n foju e wo o.
Famoodun, eni to n fesi si awon oro yi Diekola so lori redio kan nilu Osogbo nipa bi egbe APC se fidiremi nibi idibo to waye ni Iwo-oorun Osun so pe iwa ailooto si egbe ni Diekola hu.
O ni fun Diekola lati so pe oun mo on mo sisepo pelu egbe oselu alatako lati le je ki aburo Oloogbe Isiaka Adeleke wole ibo ohun je oro rirun ti ko ye ki won maa gbo lenu agba egbe.
Famoodun fi kun oro re pe idi ti Diekola fi n japoro kaakiri ni pe ko fe ki Gomina Aregbesola lenu lorii yiyan eni ti yoo di gomina eleyii to ni ala ti ko le se ni.
No comments:
Post a Comment