IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 13 December 2017

Tokede derin peeke awon eeyan ijoba ibile Boluwaduro



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Lara ona lati mu ki igbe aye rorun fawon araalu, alaga ijoba ibile Boluwaduro nipinle Osun, Omooba Hakeem Tokede ti seto iranwo owo fawon opo, awon agbalagba ati awon alaabo ara.

Yato si eleyii, Tokede tun gbe kanga igbalode si ona marun lati din wahala omi pipon kaakiri ku fawon araalu, bee lo tun pin awon nnkan elo idako fawon agbe.

Gege bi Tokede se wi, nigba tawon araalu ba ni inudidun sijoba ni ohunkohun tijoba ba n se to lee setewogba. O ni eto naa je amuse ileri toun se pelu awon eeyan ibile Boluwaduro.

Egberun lona ogun naira pelu ounje lokookan awon opo, awon agbalagba pelu awon alaabo ara ti gbogbo won je ogorun gba lojo naa.

Tokede waa ro awon odo lati yago fun iwa jagidijagan paapa lasiko yii ti idibo ijoba ibile ti n kanlekun nipinle Osun.

Alaga yii dupe lowo Gomina Aregbesola gun anfaani to fun un lati dari awon eeyan re, bee lo ro awon eeyan ipinle Osun lati rii pe dandan lowo ori je lati kun ijoba lowo ninu awon ise ribiribi to n se.

Okan lara awon ti won janfaani naa, Arabinrin Anike Dada dupe lowo Tokede fun bo se siwe iranti rere kan awon alaini, o si gbadura itesiwaju funsejoba e.



No comments:

Post a Comment