Igbimọ awọn ọdọ ilu Ilobu nijọba ibilẹ Irẹpọdun nipinlẹ Ọṣun, Ilobu Youth Assembly (IYA), ti ke si awọn agbofinro, paapaa, awọn ọlọpaa, lati tete fi pampẹ ofin mu ọkunrin ọmọbibi ilu Ifọn kan, Jamiu Adejumọ, lati sọ tẹnu rẹ lori ẹsun to fi kan ilu Ilobu laipẹ yii.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ IYA, Ẹnjinia Kọlade Ọnaọlapọ, ṣe sọ ninu atẹjade kan, ṣe ni Adejumọ ko awọn kan jọ laipẹ yii labẹ Concerned Citizens of Orolu Kingdom lati ba awọn oniroyin sọrọ, nibẹ lo si ti we oniruuru agbelẹrọ irọ jọ lati fi da omi alaafia ilu Ilobu ru.
O ni o ya awọn lẹnu bi ọkunrin naa ṣe n bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Ọṣun, to si n naka aleebu si ẹka eto idajọ lori ọrọ to ti wa niwaju ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun eleyii ti ẹnikẹni ko lẹtọọ lati sọ nnkan kan lorii rẹ labẹ ofin.
Ọnaọlapọ sọ siwaju pe ẹsun ti ko kan ilu Ilobu lọwọlẹsẹ ni Adejumọ fi kan awọn ninu ipade oniroyin naa, gbogbo aye lo si mọ pe awọn eeyan ilu Ifọn yii ni alakatakiti ti wọn kọkọ maa n da wahala silẹ lagbegbe naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe ilu Ilobu ko tii bọ ninu wahala ogun abẹle to waye kọja nibẹrẹ ọdun yii; ọpọ ẹmi lo ṣofo, ọpọ ile ni wọn jo, wọn ba dukia jẹ, bẹẹ ni awọn ọmọ ilu Ilobu bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun ni wọn ko ribi fori le mọ.
O ni ni bayii ti nnkan tun ti wa n pada bọ sipo diẹdiẹ, ko yẹ kijọba ipinlẹ Ọṣun ati awọn agbofinro faaye gba iru Adejumọ atawọn ti wọn jọ n dana ọtẹ lati tun da hilahilo miran silẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ẹka to lominira ni ẹka eto idajọ, ko si si ẹnikankan to le kọ wọn ni iṣẹ wọn. Ti wọn ba ri i pe awọn ti wọn fẹsun kan ko jẹbi ẹsun naa lẹyin iwadi, o di dandan ki wọn tu wọn silẹ nitori olootọ kan ko gbọdọ ku sipo ika.
Wọn ke si awọn ọmọ ilu Ifọn lati gba ọdọ ajọ to n ri si iṣọwọṣiṣẹ ẹka eto idajọ lọ ti ohunkohun ba ru wọn loju lori igbesẹ ti adajọ kankan ba gbe, ki i ṣe ki wọn maa sọrọ to tun le ko hilahilo ba awọn araalu.
No comments:
Post a Comment