IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 19 August 2025

Adajọ to ba tu Awiṣẹ ati Mojeed silẹ fẹẹ da ogun abẹle miran silẹ niluu Ifọn ati Ilobu ni o - CCOK


Agbarijọpọ awọn eeyan ilu Ifọn Orolu nipinlẹ Ọṣun labẹẹ Concerned Citizens of Ifon Orolu Kingdom ti ranṣẹ ikilọ si ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun lati maṣe tu awọn afurasi meji ti ọwọ tẹ laipẹ yii lori iku ọmọ ilu wọn kan, Lukman Akorede, silẹ.


Agbẹnusọ wọn, Jamiu Adejumọ, ṣalaye fun awọn oniroyin pe ti finrinfinrin ti awọn n gbọ nipa pe wọn fẹẹ gba beeli awọn afurasi naa ba lọ jẹ ootọ, o tumọ si pe ẹka eto idajọ ko nifẹ si alaafia nipinlẹ Ọṣun niyẹn.


Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, inu oṣu kẹta ọdun yii lọwọ tẹ ọkunrin kan ti wọn pe ni Tajudeen Ọdẹrinde Awiṣẹ ati Mojeeb Alani lori ẹsun iku gbigbona ti wọn fi pa Akorede.


Wọn ni ṣe ni wọn ge ori, apa, ẹsẹ, itan Akorede, wọn yọ nnkan ọmọkunrin rẹ, wọn si yọ ọkan rẹ, eleyii to tumọ si pe ki i ṣe pe wọn pa a lasan, wọn fẹẹ fi ṣetutu owo ni.


Lẹyin ti awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye fun awọn ọlọpaa ni wọn mu Awiṣẹ ati Alani, wọn si gbe wọn lọ si kootu. Bakan naa ni ẹka to n fun ile ẹjọ nimọran, DPP, sọ pe awọn mejeeji lẹjọ lati jẹ, idi si niyẹn ti adajọ kan ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun fi sọ pe ki wọn fi wọn pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ igbẹjọ wọn.


Ṣugbọn Adejumọ ni iyalẹnu lo jẹ fun awọn nigba tawọn gbọ pe adajọ miran to n dele de adajọ akọkọ to ti lọ fun isinmi bayii, ti n gbero lati fun awọn afurasi mejeeji ni beeli, o si ṣee ṣe ki wọn tu wọn silẹ laipẹ.


Adejumọ sọ siwaju pe bawo ni adajọ yoo ṣe fun awọn to n koju ẹsun ipaniyan, ti ẹri pupọ si wa lodi si wọn, ni beeli? O ni o tumọ si pe awọn araalu ko le ri idajọ ododo gba lati ile-ẹjọ mọ niyẹn, eyi to si le fa ki onikaluku maa ṣedajọ lọwọ ara rẹ.


Lorukọ awọn agbarijọ naa, Adejumọ ke si Gomina Ademọla Adeleke ati Adajọ Agba Adepele Ojo, lati tete dide si ọrọ naa, ki wọn maṣe jẹ ki wọn tu Awiṣẹ ati Alani silẹ, ki wọn ma baa da wahala miran silẹ lagbegbe ọhun.

No comments:

Post a Comment