IROYIN YAJOYAJO

Monday, 18 August 2025

Ijọba ipinlẹ Ọṣun kede ọlude fun ayẹyẹ ọdun Iṣẹṣe


Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọlude yoo wa lọjọ Wẹsidee, ogunjọ oṣu kéjọ ọdun yii lati fun awọn ẹlẹsin ibilẹ laaye lati ṣe ọdun Iṣẹṣe.


Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna AbdulRasheed Aderibigbe fi sita lo ti ni ijọba gbe igbesẹ naa lati faaye silẹ fun awọn oniṣẹṣe lati ṣe ayẹyẹ wọn daadaa.


O ni eleyii tun ṣafihan ifẹ ti gomina ni si gbogbo awọn ẹleṣin nipinlẹ Ọṣun.


Gomina ba awọn Oniṣẹṣe yọ ayọ orikadun, o si gba wọn niyanju lati ṣe ayẹyẹ nibamu pẹlu alakalẹ ofin, ki wọn si nu igbe aye iṣọkan lọkunkundun.

No comments:

Post a Comment