IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 16 August 2025

O ṣẹlẹ! N'Ileṣa, wolii ṣeleri iṣẹ iyanu miliọnu marun naira fun awọn to fi owo nla silẹ ninu isọji


Afaimọ ki wahala nla ma bẹ silẹ niluu Ileṣa nipinlẹ Ọṣun to ba di aago mẹwaa aarọ oni Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ ti a wa yii, to ba di pe ohun ti wolii kan sọ nibẹ ko ba wa si imuṣẹ.


Ileeṣẹ iranṣẹ kan ti wọn pe ni God's Favourite Ministry (Goshen Land) to wa niluu naa, labẹ idari Wolii Ọlanrwaju Favourite, la gbọ pe o ṣeto adura oniwakati mẹrinlelogun, bẹrẹ lati aago mẹfa irọlẹ ọjọ kẹẹdogun si aago méfa idaji ọjọ kẹrindinlogun.


Nigba ti adura nlọ lọwọ la gbọ pe ọkan lara awọn iranṣẹ Ọlọrun to gbe lọ sibẹ, Prophet Testimony Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Fire Daddy, kede pe oun fẹẹ fi han awọn to wa nibẹ ni wolii loun ni tootọ.


Bayii lo pe obinrin kan jade laarin ero, to si sọ fun un pe yoo ri alaati miliọnu marun naira ki awọn olujọsin too ka nọmba kinni si ikejila tan.


Ni tootọ, gẹgẹ bi ẹnikan to wa ninu iṣọji naa ṣe sọ fun Gbagedeọrọ, ki wọn too ka nọmba kinni si ikejila pari ni alaati miliọnu marun naira wọle si ori foonu obinrin yii, bayii lariwo taa.


Asiko yii ni Wolii Adeleke sọ pe ki ẹni to ba n fẹ iru iṣẹ iyanu bẹẹ jade pẹlu ẹgbẹrun lọna mọkanlelaadọrin naira (#71,000), o ni ko too di aago mẹwaa aarọ oni Satide, ẹnikọọkan wọn yoo gba alaati miliọnu marun naira.


Ẹni to ba wa sọrọ ṣalaye pe ogunlọgọ awọn to wa nibi isọji ni wọn ya sita, ẹni ti ko ni owo lọwọ wa ibi ti yoo ti ya owo, bẹẹ ni awọn miran sanwo naa latinu akanti wọn.


Amọ ṣa, ni bayii ti aago mẹwaa aarọ ku diẹ, gbogbo awọn araalu ni wọn ti ganu kalẹ lati mọ nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ.

Ohun ti ọpọlọpọ n sọ ni pe awọn yoo da wahala silẹ ti ọrọ asọtẹlẹ wolii yii ko ba ṣẹ, ṣugbọn awọn miran n sọ pe pupọ awọn wolii ọhun ni wọn ni ibaṣepọ pẹlu awọn agbofinro.

Ibi to ba yọri si, Gbagede yoo fi to yin leti laipẹ.

1 comment:

  1. Nibo lo pada yori si o. E ku isẹ takuntakun

    ReplyDelete