IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 19 August 2025

Kaadi idibo la fi maa regi mọ awọn jaguda oloṣẹlu lẹyin nipinlẹ Ọṣun - Adeleke


Gomina Ademọla Adeleke ti ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati tu yaaya jade gba kaadi idibo alalopẹ to wa lode bayii.


O ni ọna kan ṣoṣo ti wọn fi le jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn ti n ni iriri iṣejọa rere labẹ iṣakoso oun ni ki wọn gba kaadi idibo ti yoo fun wọn lanfaani lati kopa ninu idibo gomina to n bọ lọna.


Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina, Mallam Ọlawale Rasheed, fi sita, lo ti ni, yatọ si gbigba kaadi idibo, awọn araalu tun gbọdọ daabo bo ibo wọn lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026 ti ajọ INEC ti la silẹ fun ibo gomina l'Ọṣun.


O ni 'A gbọdọ ṣetan lati regi mọ awọn jaguda oloṣelu lẹyin nipasẹ didaabo bo ibo wa lọjọ naa, a ko gbọdọ faaye gba wọn lati dabaru erongba ọkan wa.


'Oniruuru itẹsiwaju ati idagbasoke lo ti ba ipinlẹ Ọṣun lati bii ọdun meji aabọ sẹyin, nnkan rere yii ko si gbọdọ dawọ duro, idi niyẹn ti a fi gbọdọ kopa ninu eto iforukọsilẹ yii, ka le lanfaani lati fi ibo wa gbe ẹni to wu wa wọle.'' 


Adeleke ke si awọn adari kaakiri ijọba ibilẹ lati ri i daju pe awọn eeyan wọn to ti to ibo di tu jade fun gbigba kaadi idibo alalopẹ fun itẹsiwaju ijọba to duroore.

No comments:

Post a Comment