Ọwọ awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun ti tẹ baba agbalagba kan, Sodiq Adeleke, lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹfa lo pọ.
Ilu Ọdẹomu nijọba ibilẹ Ayedaade ni ọwọ ti tẹ baba ẹni ọgọta ọdun naa laipẹ yii.
Gbagedeọrọ gbọ pe ṣe ni baba yii fi owo tan ọmọdebinrin naa wọnuu yaara rẹ.
Bi ọmọ ṣe wọle ni baba yọ 'kinni' si i, to si ba a laṣepọ.
Nigba ti aṣiri tu, wọn fa baba yii le awọn Amọtẹkun lọwọ, o si jẹwọ pe loootọ loun huwa buburu naa.
O ni igba akọkọ niyẹn ti oun yoo ṣe iru rẹ, ki wọn fori jin oun.
Amọ ṣa, alakoso ajọ Amọtẹkun l'Ọṣun, Oloye Adekunle Ọmọyẹle, ti sọ pe ni kete tiwadii ba ti pari lori ọrọ baba naa ni yoo foju bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment