IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 13 September 2025

Ọba Jimoh Oyetunji Ọlanipẹkun bẹrẹ ayẹyẹ ọdun kẹẹdogun lori itẹ


Oniruuru eto ni wọn ti la silẹ bayii lati fi ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun kẹẹdogun ti Ataọja ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Ọlanipẹkun, Larooye Keji, de ori itẹ awọn babanla rẹ.


Ayẹyẹ ọlọsẹ kan ọhun lo bẹrẹ pẹlu adura pataki ni Mọṣalaaṣi apapọ ilu Oṣogbo lọjọ kejila oṣu Kẹsan ọdun yii. Nibẹ ni gbogbo awọn ọmọ ilu Oṣogbo ti ba Ọba Jimoh dupẹ lọwọ Ọlọrun fun alaafia ati oniruuru idagbasoke to ba ilu wọn latigba to ti de ori-itẹ.


Gẹgẹ bi alakalẹ eto ti wọn gbe kalẹ ọhun ṣe ṣalaye, idupẹ nilana ẹsin ibilẹ yoo waye ni Idi-Ilẹkẹ Temple, Olugun, lagbegbe Atẹlẹwọ niluu Oṣogbo lọjọọ satide, ọjọ kẹtala oṣu yii, nigba ti isin idupẹ yoo waye ni All Saints Cathedral, Balogun Agoro lọjọ Sannde, ọjọ kẹrinla oṣu yii kannaa.


Ọjọ Mọnde, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹsan ni idanilẹkọọ kan yoo waye ninu ọgba Fasiti Ọṣun, ẹka ti ilu Oṣogbo labẹ akorii Ojuṣe awọn ọba alaye lorileede Naijiria labẹ ofin ninu iṣejọba tiwantiwa, Amofin Kunle Adegoke si ni oludanilẹkọ lọjọ naa.


Idije ninu ede Yoruba laarin awọn akẹkọọ ni yoo kọkọ waye laarọ ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹsan laafin Ataọja, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ninu ere bọọlu yoo waye lọsan ni Ataọja High School, Oṣogbo.




Lọjọ wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹsan ni ayajọ ọjọ Adirẹ laafin Ataọja, nigba ti ayẹyẹ ikojade iwe kan to yannana igbe-aye Ọba Larooye Keji, ti wọn pe akori rẹ ni Crowned By Fate, yoo waye ni De-Distinguished Events Centre, Iwo Road, Oṣogbo lọjọ Fraidee, ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹsan laago mọkanla aarọ.


Ọjọ Satide, ogunjọ oṣu Kẹsan ni aṣekagba ayẹyẹ nla naa, nibẹ ni wọn yoo ti ṣajọyọ oniruuru awọn nnkan isẹmbaye ti Eledua fi jinki ilu Oṣogbo ni Technical College laago mẹwaa aarọ.


Ọdun 2010 ni Ọba Ọlanipẹkun, ẹni to jẹ Ataọja kẹrindinlogun niluu Oṣogbo, gori itẹ awọn baba-nla rẹ.

No comments:

Post a Comment