IROYIN YAJOYAJO

Monday, 8 September 2025

Idi ti a fi pinnu lati ṣatilẹyin fun Benedict Alabi - Awọn agbaagba ẹgbẹ APC ni Aarin-gbungbun Ọṣun


Awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lagbegbe Ila nipinlẹ Ọṣun ti ṣapejuwe igbakeji gomina ana, Benedict Alabi, gẹgẹ bii olootọ, ẹni ti ko jin ọga rẹ, Adegboyega Oyetọla, lẹsẹ ni gbogbo asiko ti wọn wa nijọba.


Wọn sọ pe ohun to wọpọ ninu iriri kaakiri ni wahala laarin gomina ati igbakeji rẹ, ṣugbọn pẹlu iwa irẹlẹ ati itẹriba ni Alabi fi lo ipo naa, anfaani nla ni yoo si jẹ fun ipinlẹ Ọṣun ti iru eeyan bii tiẹ ba di gomina.


Lasiko ti Alabi ṣabẹwo si awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni agbegbe Aaringbungbun Ọṣun, iyẹn Ila, Ifẹlodun, Boripẹ, Odo-Ọtin ati Oṣogbo, ni gbogbo wọn gba a tọwọtẹsẹ, ti wọn si ṣeleri atilẹyin fun un.


Niluu Ila, awọn aṣaaju ẹgbẹ bii Alagba Oyegoke, Honourable Ọbawale, Oloye Ademọla Adefila ati Oloye Bayọ Oyekanmi, sọ pe oloṣelu to ni iwa adari ni Alabi nitori ẹni to ba le ṣiṣẹ labẹ ẹlomiran lai si ikunsinu tọ si ipo adari.


Wọn sọ pe oniruuru iriri ti Alabi ti ni gẹgẹ bii igbakeji gomina ti muraa rẹ silẹ fun ipo gomina, oriire si ni yoo jẹ funpinlẹ Ọṣun ti ẹgbẹ oṣelu APC ba le fun un ni tikẹẹti.


Bakan naa ni ọrọ ri lagbegbe Ifẹlodun, Boripẹ, ati Odo-Ọtin nibi ti ọkan lara awọn agbaagba wọn, Comrade Pọju Oduọla ti sọ pe ti idibo abẹle ba waye lonii, Alabi ni oun yoo mu.


Ọrọ ko yatọ niluu Oṣogbo, gbogbo wọn sọ nipa ipa ribiribi ti Alabi ko lasiko ajakalẹ arun Covid-19, wọn ni adari to mu ọrọ igbayegbadun awọn araalu lọkunkundun ni ọkunrin oloṣelu ọhun.


Ninu ọrọ rẹ, Benedict Alabi dupẹ lọwọọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC fun bi wọn ṣe ṣatilẹyin fun un. O ni afojusun oun ni iṣọkan ẹgbẹ oṣelu naa, itẹsiwaju ati idagbasoke ipinlẹ Ọṣun.


Alabi ṣeleri lati tubọ mu ki iṣejọba rere ti gbogbo eeyan mọ ẹgbẹ APC mọ tẹsiwaju nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ lo pinnu lati lo iriri rẹ ninu oṣelu fun igbega ipinlẹ Ọṣun.

No comments:

Post a Comment