Ọkan lara awọn oṣere tiata ilẹ wa nni, Ridwan Ọlamilekan Ajilẹyẹ lo ti jade laye lẹyin ọsẹ meji tiyawo rẹ bimọ tuntun.
Ridwan, ọkan lara awọn ọmọ agba oṣere niluu Oṣogbo, Alhaji Yẹkinni Ajilẹyẹ, lo jade laye laarọ ọjọ Satide to kọja.
Ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun yii ni Ridwan, ẹni ti wọn tun maa n pe ni Baba Halima, kede pe iyawo oun bimọ tuntun, ṣugbọn kayeefi lo jẹ pe ko ba ọmọ naa jinna to fi faye silẹ.
Ridwan lo ṣe fiimu Eṣu Awẹle, bẹẹ lo tun wa lara Ajilẹyẹ Cultural Group ti baba rẹ da silẹ.
Gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ ni wọn ṣedaro rẹ, wọn ni lootọ lo ṣaisan kekere, ṣugbọn ko sẹni to gbagbọ pe o le yọri si iku.
Wọn ti sinku Ridwan laarọ ọjọ Satide ọhun ni Oke-Ayepe niluu Oṣogbo.
No comments:
Post a Comment