IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 17 October 2015

Ajo EFCC ti gbe Akpabio


Ajo to n gbogun ti awon ti won se owo ilu basubasu, EFCC ti fi panpe won gbe gomina tele funpinle Akwa Ibom, Godswill Akpabio lori esun pe o se owo to le ni ogorun kan bilioonu naira basubasu laarin osu kinni si osu kejila odun 2014.
Akpabio, eni to je olori ileegbimo asofin agba fawon omo egbe oselu to kere ju ni agbejoro kan, Leo Ekpenyong fiwe esun re sowo si ajo EFCC ati Aare Buhari pe o gbodo wi tenu e lorii bo se pa owo ilu ni ponpo lasiko isejoba re.
Idi si niyii ti ajo EFCC fi gbe seneto naa ni nnkan aago merin aabo irole ojoo Fraide, agbejoro re, Ogbeni Rickey Tarfa ni won jo lo sibe nibi to ti so pe iro to jinna soooto ni gbogbo nnkan ti olufisun oun ko sinu leta naa.

No comments:

Post a Comment