IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 17 October 2015

Awon Boko Haramu ti n be Buhari fun ijiroro


Aare Mohamodu Buhari ti so fawon oniroyin pe awon asaaju iko Boko Haramu ti n be oun lati jo joko papo fun ijiroro lori oro awon omobinrin ileewe Chibok ti won ji gbe.
Buhari ni oun mo ibi tawon omo naa wa sugbon isoro toun ni lori oro naa ni ona lati mu awon omo naa jade laaye laisepe won yoo ba ogun tawon yoo gbe ko awon ti won ji won gbe loju lo.
O ni loooto lawon asaaju Boko Haramu ti fe ijiroro sugbon oun fe ki won fi da on loju pe aaye lawon omo naa wa koun too ba won joko papo lati mo oun tijoba peluu won yoo fi se pasipaaro fun emi awon omobinrin ti won le ni igba naa.

No comments:

Post a Comment