Ariwo ikunle abiamo ni gbogbo awon eeyan agbegbe Ogbere nikoja Ijebu Ode nipinle Ogun nke nirole oni nigba ti moto boosi elero mejidinlogun kan ko sinu odo Arun to wa nilu naa.
Ko tii si eni to moye awon ti won wa ninuu boosi naa sugbon alukoro ajo NEMA, Ogbeni Ibrahim Farinloye fidi isele naa mule.
Farinloye salaye pe ajo NEMA pelu ijoba ipinle Ogun, ijoba ibile Ila-oorun Ijebu, awon eso ojuupopo atawon olopa n sise takuntakun nibe lowolowo lati yo awon ti won wa ninu oko naa.
A oo ranti pe boosi elero mejilelogbon to ko awon ti won n lo sibi igbeyawo lo ko sinu odo naa lodun 2012, eeyan mejilelogun lo si ku nibe nigba naa.
Thursday, 15 October 2015
Boosi elero mejidinlogun ko sinu odo Arun nipinle Ogun
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment