IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 15 October 2015

Obalufe ti ku


Leyin nnkan bii osu meta ti Ooni ilu Ileefe, Oba Okunade Sijuwade waja, eni to je igbakejii re, Oba Solomon Folorunso Omisakin tii se Obalufe ti Iremo Quarters nilu Ileefe naa ti jade laye.
Laaro yii la gbo pe baba dake nileewosan OAUTHC, Ileefe leyin to lo odun metalelogorin laye.
Baba yii ni olori awon afobaje tilu Ileefe nigba aye re, gbogbo oju lo si wa laraa re latigba ti idije lorii eni ti yoo je Ooni tuntun ti bere nitori pe oun ni asa fagbara fun lati kede oruko eni ti won ba mu nigbeyin.

No comments:

Post a Comment