IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 28 October 2015

L'Osogbo, birikila yaju si kootu, ladajo ba ju u sewon osu meta

Adajo majistreeti kan nilu Osogbo, F.A. Sodamade ti pase pe ki won ju omokunrin birikila kan sewon osu meta lori esun pe ko bowo fun ile ejo pelu bo se mo on mo salo lojo to ye ko wa fun igbejo esun ti won fi kan an.
Ganiyu Abolubode eni odun metadinlogoji lo n jejo esun kan to nii se pelu oro ile ni majistreeti naa, ti won si sun igbejo re siwaju di ojo keje osu kewa odun yii.
Sugbon nigba ti ojo naa pe, akowe kootu pe oruko omokunrin yii lati bo sinuu gala igbejo sugbon won ko ri eegun to n je ajike titi ti adajo fi dide lojo naa pelu ase pe kawon olopa rii daju pe awon gbe e de kootu lose to koja.
Lojo Aje to koja ti won gbe Ganiyu wa si kootu ni agbejoro funleese olopa, Agboola Waheed so pe olujejo yaju si ile ejo pelu iwa afojudi to hu naa.
O ni iwa re ohun lodi si ofin iwa odaran tipinle Osun ati pe ijiya nla si wa fun un labe ofin odun 2003 tipinle Osun n lo.
Nigba ti won beere lowoo Ganiyu boya o jebi esun naa tabi ko jebi, o ni oun jebi sugbon ki adajo siju aanu wo oun. O ni oun ko mo on mo yaju sile ejo sugbon owo ileewe awon omo oun loun se wahala re lo lojo keje osu kewa to ye koun farahan nile ejo.
Nigba to n gbe idajo re kale, F.A. Sodamade ran olujejo sewon osu meta sugbon o faaye faini egberun lona marun naira sile fun un.

No comments:

Post a Comment