Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti gbosuba fun aare ana lorileede yii, Omowe Goodluck Ebele Jonathan lorii ipa to ko lati fi ofin de kikola fawon omobinrin lorileede yii.
Aregbesola soro naa nigba to n soro nibi eto kan ti ajo United Nations Fund for Population Activities (UNFPA) ati Shericare Foundation (SCARF) se lorii bi kikola fawon omobinrin se n gbile sii.
O ni bi Jonathan se so dida abe fawon omobinrin lorileede yii di ofin eleyii to mu ijiya nla lowo je eyi to ye ki gbogbo aye gbosuba fun nitori pe igbese naa buru jai.
Gege bi Aregbesola se wi, 'Ohunkohun to wu ka so nipa isejoba Jonathan, o ye fun kiki pelu igbese to gbe lorii dida abe fawon omobinrn wa. Asa yii je eyi to buru lopolopo, gbogbo ona ti yoo si fi pare lorileede wa lo ye ka maa san bayii.
'Yato si ewu to wa ninu kikola fawon omobinrin, oniruuru aisan lo tun n tipase re wole soju ara won bayii, idi niyi ti gbogbo ijoba lekajeka fi gbodo gbe igbese ti yoo pa asa naa re patapata lorileede Naijiria."

No comments:
Post a Comment