IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 November 2015

Nitori owo ori; Aregbesola tilekun ileese ijoba apapo marun l'Osun

Ileese to n pawo wole labenu funjoba ipinle Osun, Osun State Internal Revenue Service (OSIRS) ti fi agadagodo si marun ninu awon ileese to je tijoba apapo to wa nilu Osogbo lori esun pe won je ijoba ni obitibiti owo ori.
Lose to koja ni adele alaga ileese naa, Ogbeni Dayo Oyebamji ko awon eeyan re sodi loo ti awon ti won so pe won ya koloransi ohun, pelu ileri pe awon sese n meye bo lapo fawon ileese ijoba apapo naa ni.
Owo ori to le ni milioonu lona metadinlogun la gbo pe ileese elepo NNPC je ijoba ipinle Osun laarin odun 2008 si 2013, nigba ti banki awon agbe, iyen Bank of Agriculture je owo to le ni milioonu lona metalelogoji naira laarin odun 2006 si 2013.
Won tun ti ileese National Centre for Technology Management (NACETEM), to wa ninu ogba Obafemi Awolowo University (OAU), Ile-Ife ti won je owo ori to le ni milioonu merindinlogoji naira laarin odun 2006 si 2013, African Regional Centre for Space Science Technology, OAU, Ile-Ife ni tie je owo ori to to milioonu lona ogorin naira laarin 2006 si 2011, nigba ti International School, OAU campus je milioonu mokanlelogbon naira laarin 2006 si 2011.
Oyebamji ni awon gbe igbese naa leyin tawon gbe ejo won lo sile ejo, ti ile ejo si faye lagbara lati loo ti won pe nitori pe won ko kobiara si sisan awon owo ori ti won je ohun.

No comments:

Post a Comment