IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 25 November 2015

Latari wahala ojoojumo; igbeyawo olodun marun tuka n'Ileefe


Arabinrin Bola Adeniyi ti ro awon adajo kootu kokokoko kan nilu Ileefe lati tu igbeyawo olodun marun to wa laarin on atoko re, Seun Adeniyi ka bayii.
Gege bi obinrin olomo meta naa se so lojo kerindinlogbon osu kewa odun yii to koko lo sile ejo, ko si ifokanbale kankan fun un lati odun marun to ti fe oko re.

O ni odun 2010 lawon segbeyawo, omo meta lawon si ti bi. Omo odun mejo ni Ayomide to je akobi, omo odun mefa ni Oluwasekanmi to je ekeji, nigba ti abikeyin won, Oluwadunsin je omo odun kan ataabo.
O fi kun oro re pe ti oko oun ba ti bere wahala re bayii, oniruuru awon nnkan ija oloro bii ada ati obe ni yoo maa fi le oun kaakiri, ti yoo si maa leri pe afi dandan koun gbemi oun.
Lara awon eleri ti obinrin yii pe ni iya re, Arabinrin Racheal Adewole, iya naa ro ile ejo lati tu igbeyawo omo re ka.
O ni ko ma baa di pe awon eeyan yoo maa da oun lebi lori oro naa leyin to ba da emi omo oun legbodo pelu wahala ojoojumo to maa n fa ninu ile.
Nigba ti won beere ohun ti oko nii so si ejo tiyawo re pe, Ogbeni Seun Adeniyi ni iro niyawo oun pa, ati pe oro re ti su oun gan an nitori onijangbon obinrin ni, o ni oun naa faramo ki won tu igbeyawo olodun marun ohun ka.
Nigba to n gbe idajo re kale, Adajo kootu naa, Oloye Abioye Olatunbosun ni niwon igba ti ko ti si ife mo laarin awon mejeeji, oun tu igbeyawo naa ka laisepe oko yoo san owo ori pada rara.
O pase pe kiyawo maa ko awon omo meteeta lo fun itoju gege bii obinrin, ati pe ileewosan ijoba lo gbodo maa gbe won lo nigbakuugba ti won ba saisan.
Ni ti oko, ile ejo ni o gbodo maa san egberun mewa losu funyawo e funtoju awon omo naa ati pe yoo maa gbe gbogbo bukata loribeto eko won.
Oloye Olatunbosun waa ro awon tokotaya naa pe niwon tigbeyawo won ti tuka, ko gbodo si gbonmi sii omi o too kankan mo laarin won nigbakuugba ti won ba pade.

No comments:

Post a Comment