Owo ajo sifu-difensi ipinle Osun ti te baba eni odun mejilelaadota kan, Kareem Kudomi toun atomo re okunrin, Sarafa Kudomi omo odun mokanlelogun ti jingiri ninuu igbo tita.
Gege bi alukoro ajo naa, Ogbeni Wale Folarin se salaye, ilu Akure nipinle Ondo ni baba atomo re yii ti loo ra igbo to din die ni kilogiraamu meje, won si gbe e wa sipinle Osun.
Ilu Okuku nijoba ibile Odo-Otin nipinle Osun ni won gbe igbo naa lo lati ta a fun onibara won kan nibe sugbon ninu ilee akoku kan ti won farapamo si de onibara wo lowo ti te won.
Yato si baba atomo re tiwadi fi han pe o je omoleewe gbogbonise kan nipinle Osun, omokunrin kan to n je Samson Peter ati Opeyemi tun wa nibe lojo naa sugbon won ti tete juba ehoro ko too di pe awon sifu difensi debe lojo naa.
Folarin ni ajo sifu difensi ti fa awon mejeeji le ajo to n dode nu awon ti won ba n gbin tabi ta igbo, iyen Nigeria Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) lowo.
O ni gbogbo ipa lajo naa yo sa lati rii pe awon araalu se nnkan to tona, to si ba ofin orileede yii mu.
Tuesday, 24 November 2015
L'Okuku, owo te baba atomo ti won n tagbo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment