IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 4 November 2015

L'Osogbo, Sodiq atoree re ji eru ijoba, ni won ba foju bale ejo

Owo ileese olopa ipinle Osun ti te awon omokunrin meji laipe yii lori esun pe won ji awon eru to je tileese Osun State Waste Management Agency (OSWMA), leyin ti won si ro tenuu won tan fawon olopa ni won foju bale ejoo majistreeti tilu Osogbo laipe yii.
Awon olujejo naa, Sodiq Mukaila omo odun mejidinlogun ati Opeyemi Obaniwa toun naa je omo odun mejidinlogun tiwadi fi han pe won je omoleewe girama nipinle Osun ni won fesun kan pe won lo sibi ti ajo OSWMA maa n ko eru si lagbegbe Onibueja nilu Osogbo lojo kokandinlogun osu kewa odun 2015, ti won si loo ji awon eru kan ko nibe.
Esun meji otooto to nii se pelu igbimopo huwa buburu ati ole jija nileese olopa nipase Inspekito Fagboyinbo Abiodun fi kan awon olujejo.
Fagboyinbo salaye pe awon omo naa pelu awon yooku won ti won ti salo bayii ji awon nnkan to n lo ina bii main switch board electric control box, electric motor to koja sidii palletize ati bee bee lo.
O ni iwa buburu tawon omo naa hu lodi, o si nijiya nla labe ofin iwa odaran ti odun 2003 tipinle Osun n lo.
Nigba ti akowe kootu ka awon esun mejeeji sawon omo naa leti, won ni awon ko jebi, bee ni agbejoro won, Arabinrin Raji Abiodun ro kootu lati faaye beeli sile fun won pelu ileri pe won ko nii salo fun igbejo nigbakiigba tile ejo ba pase pe ki won yoju.
Nigba to n gbe idajo re kale, adajo majistreeti naa, Olusola Aluko faaye beeli sile fun won pelu egberun lona otalelugba naira ati oniduro meji-meji ni iye kannaa.
Aluko ni awon eleri naa gbodo maa gbe lagbegbe ile ejo ati pe ki awon olopa sewadi adiresii won daada, leyin naa lo sun igbejo siwaju di ogunjo osu kokanla odun yii.
Sugbon se ni iya okan lara awon omodekunrin naa bu sekun gbaragada ni kootu nigba ti awon olopa tun fowo taari ipako omo re sinuu moto nitori pe ko si enikeni
nitosi lati se oniduro fun un.

No comments:

Post a Comment