IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 5 November 2015

Nipinle Eko, awon olopa n wa 'ejo' to gun Saheed lobe pa

Ileese olopa ipinle Eko ti n wa omodekunrin kan toruko re n je Saka Ahmed sugbon ti gbogbo eeyan mo si 'ejo' latari bo se gun Saheed Jimoh lobe laya, tiyen si gbabe ku.
Ileewe Gaskiya College lagbegbe Ijora nipinle Eko ni Saka ati Saheed nlo, SS2 la gbo pe Saka wa nigba ti Saheed omo odun mokandinlogun wa ni SS3, to si tun je okan lara awon oloye nileewe naa.
Ese kan la gbo pe 'ejo' se nileewe lojoo Tusde to koja yii to mu ki Saheed da seria fun un gege bii okan lara awon oloye.
Saka di oro yii sinu, o si pinnu lati fiya je Saheed lojo keji. Ile ounje kan to wa nitosi ileewe won ni 'ejo' lugo de Saheed si, biyen si se fee wonu ileewe laaro ojoo Wesde ni Saka pe e, o si gbe ija ko o loju.
Bi won se bere ija ni 'ejo' kowo bonuu baagi re, o mu obe jade, o si fi gun Saheed laya, ki awon eeyan ti won wa nitosi si too gbe Saheed deleewosan, elemi ti gba a, o ti ku patapata.
Latigba naa ni won si ti n wa 'ejo' kaakiri.

No comments:

Post a Comment