IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 17 November 2015

Oluko Poli Iree para e sinu ile .Majele lo koko gbeje, leyin naa lo gunra e lobe pa


Agbosogbanu niroyin iku okan pataki lara awon oluko ile eko gbogbonise tilu Iree nijoba ibile Boripe nipnle Osun je fun awon egbe e atawon akeko, bee lo je kayeefi fun gbogbo awon to gbo nipa e.
Yato si pe oluko yii, Samson Adegbesan Adetoye ko saisan rara lasiko to ku yii, ese araa re lo fi rin kuro nilee re to wa lagbegbe Mallam Tope Furniture ni Ring Road nilu Osogbo, leyin to dagbere ibiise funyawo re lo wo moto lo silu Ileefe nibi to ti loo gbemi araa re.
Adetoye, eni to ti n sise oluko ni eka awon akowe ofiisi, iyen Department of Office Technology Management (OTM) nile eko naa lati opo odun seyin, lawon eeyan sapejuwe gege bii onisuuru ati eni ti kii ko ore.
Odun die seyin la gbo pe iyawo akoko ti okunrin yii fe jade laye, leyin naa lo feyawo miin ti won jo n gbe bayii, Olorun si fi awon omo rere jinnki e, koda, okan lara awon omo re n se agunbaniro lowolowo bayii.
Gbogbo ose to koja lohun lo wa nileewe, to si n ko awon omo lekoo, ko si seni to mo pe kinnikan n se okunrin naa labe aso tori ko yan oro naa leti enikankan rara to fi gbe igbese iku.
Laaro ojoo Tusde to koja, iyen ojo kewa osu kokanla odun ti a wa yii, Adetoye dagbere ileewe fun iyawo re, o si so pe oun ko fee gbe moto lo boya nitori oro owongogo epo petiroolu to wa ninu ilu.
Sugbon dipo kokunrin eni odun mejidinlogota yii loo wo moto Iree, moto Ileefe lo wo, o si forile ilee re kan to wa n'Ife.
Nigba to debe, o koko ko leta sile pe aye ti su oun, oun ko lee farada a mo, ki gbogbo awon eeyan darijin oun. Leyin naa lo da majele kan mu sugbon nigba to rii pe majele naa ko tete sise, o mu obe kan, o si bere sii fi gun araa re laipariwo titi ti emi fi jade lara e.
Awon ti won wa nitosi nigba to de ni won sakiyesi pe o ti duro pe ju ninu ile, nigba ti won yoo si fi debe, Adetoye ti rekoja odo, akuko ti ko leyin olomokunrin.
Bayii ni won gbe oku re lo sile igbokusi ti Obafemi Awolowo Teaching Hospital, ko too di pe won fi eeru fun eeru lojoo Fraide ojo ketala osu kokanla ti a wa yii nile re to ku si n'Ife.
Ki waa lo le pa Adetoye nibeere to wa lenu gbogbo awon osise atawon akeko Poli naa, bo tile je pe se ni gbogbo awon oluko ibe, paapa awon alakoso se oro naa ni wiwo lenu awoo wo, sibe iwadi fi han pe o see se ko je airowo osu gba deede lo ran okunrin naa lorun aremabo.
Gege bi osise kan se so nibe, 'ijoba lo pa okunrin yen, nigba ti eni ti ko ni ona abuja miin yato si owo osu ko ba ri owo gba fun odidi bii osu meje, o lomo nile ti won wa nileewe giga, o si niyawo, bee lawon molebi naa wa nile, bawo ni ko se nii ronu para e.
'O kan je pe ko foro re lo enikeni ni, iba mo pe airinjinna ni ko je ka rabuke okere, ko seni ti ko kan rara, onikaluku wa kan gba kamu ni, gbese lo rerere ni banki ati alajeseku kaakiri, ki leeyan waa fee se ju ko gba fun Olorun lo.
'Abi eni ti ko saisan rara, to waa ko leta pe aye su oun, oun ko lee farada mo, taani ko saimo pe ina an to ga ju emi e lo lo n joo labe aso, afi ki Olorun gba wa o'.
A oo ranti gege bi Alaroye se fi to yin leti pe leyin nnkan osu meje tawon oluko ileewe to je tijoba ipinle Osun ti wa lenu iyanselodi nijoba too ri tiwon ro, ti won si jo sadehun lose meta seyin pe ki won segile iyanselodi naa pelu ileri pe won yoo gba owo naa.

No comments:

Post a Comment