IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 23 December 2015

Afi ki Buhari se jeje lori oro Biafra o- Gani Adams

Alakoso apapo fun egbe Oodua Peoples' Congress (OPC), Oloye Gani Adams ti fa ijoba apapo leti lori oro awon eya Igbo kan ti won n pe ni Biafra ti won n so pe awon fee pinya kuro lara orileede yii.
Gani Adams ni pelepele ti ejo n gun ope nijoba apapo gbodo fi oro naa se nitori pe didun kukulaja ati pipa awon eeyan yii ko lee so eso rere kankan fun itesiwaju orileede yii.
Adams soro ikilo yii lasiko ti egbe awon asojukoroyin lorileede yii eka tipinle Osun fun un lawoodu nilu Osogbo lose to koja gege bii asoju to dangajia lori oro asa, Cultural Ambassador.
O ni ko si ofin to de ipinnu enikeni lorileede yii, nigba ti oro ba si ti ri bayii, ohun tijoba nilo lati se ni ki won pe awon eeyan yii nitubinnubi, ki won si jo so oro naa lasoyan.
Gege bo se wi, "Awon eeyan yii leto si ipinnu araa won gege bo se wa ninu ofin ile Adulawo ati ofin United Nations. Orileede kan wa lara United Nations ti awon eeyan re ko ju egbern lona aadota lo, sansan si ni asia won duro nibe, opolopo awon orileede lo si wa ni West African Nations tawon eeyan won ko to egberun lona aadota.
"N ko so pe mo faramo iyapa o, sugbon ohun ti mo n so ni pe a ko lee fi dandan mu eya kankan lati wa ninu isokan orileede Naijiria, a gbodo pe won, ka si gbo edun okan won.
"A gbodo lee pe won ba soro; se e le gba agbegbe (regionalism) ati bee bee lo, awon ona ti a le gba ba won soro niyen, kii se tipatikuuku. Orileede Britain ko gbodo ti Scotland nigba to fee ya kuro lara Britain, awon eya kan naa si wa ti won fee ya kuro lara Spain bayii, won ko lo agidi le won lori.
"Pipa awon eya Igbo ko lee mu ojutu ba oro to wa nile yii, ohun to sele ni Onitsha laipe yii ko bojumu rara. Se lawon olopa dede loo yinbon pa marun ninu awon eeyan ti won n fidunnu han lojuupopo.
"Mo ro pe o ye ka ba awon agbofinro wa soro, iwa ki won dede maa yinbon si awon araalu lainidi ko bojumo, a ko si gbodo faaye gba a lasiko ijoba tiwantiwa ti a wa yii.
O waa parowa si gbogbo omo Oodua lati se araa won losusu owo, ki won si mu igbega asa lokunkunkun nibikibi ti won ba de lorileede aye.
Ninu oro tire, alaga awon asojukoroyin nipinle Osun, Gbenga Faturoti salaye pe egbe naa mo ipa ribiribi ti Gani Adams nko lori agbende ati igbelaruge asa lorileede yii, idi niyii ti won fi pinnu lati fi ami eye naa an da a lola.
Lara awon ti won pese sibi eto naa ni Oludo ti Ido-Osun, Oba Aderemi Adedapo ati Oluwo ti ilu Iwo, Oba Rasheed Adewale Akanbi, asoju oba Ila-Orangun, alaga egbe awon oniroyin nipinle Osun, Comrade Biodun Olalere, Alhaji Semiu Okanlawon tii se oludari eto iroyin fun Gomina Aregbesola atawon eeyan miin.

No comments:

Post a Comment