IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 29 December 2015

Awon olopa n wa Sunday to gun orebinrin re lobe pa lojoo keresi


Ileese olopa ipinle Eko ti n wa omokunrin kan toruko re n je Sunday lori esun pe o gun orebinrin re, Cecilia Joseph lobe pa lojo ayeye keresimesi to koja yii.
Ninu ilee Sunday to wa ni Waterside Street ni Lakeview Estate, Phase 2 nijoba ibile Amuwo Odofin nipinle Eko nisele naa ti sele.
Ohun ti ko to nnkan la gbo pe o fa ede aiyede laarin awon ololufe yii, Cecilia omo odun mokanlelogun lo koko loo mu obe lati fi hale mo Sunday sugbon Sunday gba obe yii lowo e, o si fi gun un leyin orun.
Nigba tawon araadugbo gbe e deleewosan ni won so fun won pe o ti jade laye, latigba naa si ni Sunday ti juba ehoro.

No comments:

Post a Comment