Manigbagbe ni ojoo satide to koja, iyen ojo kerindinlogbon osu kejila odun yii je fawon eeyan ilu Modakeke, beeyan ba si gesin ninuu won ko nii kose rara.
Ojo nla yii ni won gbalejo Ooni tuntun, Oba Enitan Ogunwusi, Ojaja keji nibi ayeye olodoodun ilu naa ti won pe ni Akoraye Day.
O n bo, ko nii wa ni ariyanjiyan to koko nlo kaakiri ilu laaro ojo naa sugbon iyalenu lo je fun won nigba tawon eeyan bere sii sare kabakaba kaakiri pe Ooni Ogunwusi ti de sibi ayeye naa.
Kia niroyin ti tan kaakiri, gbogbo awon ti won ko nii lokan lati lo sibi ayeye ohun bere sii tilekun ile ati soobu won, gbogbo won si n lo sibi ayeye naa lati foju ganni Ooni tuntun.
Ariwo 'O ti see se' lawon eeyan n pa nigba ti Ooni Ogunwusi sokale ninu moto boginni to gbe lo sibe, koda, erin muse to n jade lenuu re fi han pe inu tie gan an dun yato lojo naa.
Bi awon onilu se n kii ni mesan-mewa lawon obinrin naa tu keke ijo kale lati ki kabiesi kaabo sibi ayeye Akoraye Day.
Nigba ti asiko to fun Ooni lati ba awon eeyan Modakeke soro, se ni ohun gbogbo pa lolo, ti gbogbo won si n reti oro itunu ti yoo ba won so.
Ooni Ogunwusi so fawon eeyan naa pe ko si ogun mo, bee ni ija ti dopin laarin ilu mejeeji, o ni se ni kawon eeyan ilu Modakeke fowosowopo pelu oun ati pe ohun gbogbo to dabi eni pe o ti wo yoo di tito pada.
Ooni fi kun oro re pe niwon igba to je pe Olorun nikan ni kii ja eda kule, ti eeyan ba ti gbekele Olorun ninu ohun gbogbo, o di dandan ko ba aseyori pade nibe. O ni ife ati alaafia loun fe kawon eeyan ilu mejeeji fi maa gbe.
Tuesday, 29 December 2015
Ooni Ogunwusi lo sibi ayeye Akoraye Day; lo ba ni ko sogun mo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment