IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 8 December 2015

Ibon onike ni Biola atawon ore e fi deruba obinrin lati fipa ba a lopo; ladajo ba ni ki won loo se keresi logba ewon


Adajo kootu majistreeti kan nilu Ileefe ti pase pe ki awon omokunrin meta kan loo se faaji odun keresimesi tiwon logba ewon latari esun pe won fipa ba omo odun metadinlogun lo po.
Awon omokunrin meteeta ti won fesun kan ohun ni Biola Akinwande to je omo odun mejidinlogun, Ayoola Awodile toun je omo odun meedogbon ati Sodiq Oyedele to pe araa re lomo odun mokandinlogun.
Gege bi agbejoro funleese olopa lori esun ti won fi kan won, Kopura Ronke Badmus se salaye funle ejo, ojo kejilelogun osu kokanla odun yii lawon olujejo huwa naa ni nnkan aago meji osan.
Ibon onike alawo funfun kan ati ada la gbo pe won yo si omobinrin omo odun metadinlogun ti won foruko bo lasiri naa lojule kokandinlogbon ladugbo Oke-Atan nilu Ileefe, ko too di pe won fipa ba a lasepo.
Gege bi kopura naa se wi, iwa ti won hu ohun lodi si ofin iwa odaran orileede yii ati pe ijiya to lagbara wa fun enikeni to ba san iru aso bee soro labe ofin tipinle Osun n lo lati odun 2003.
Agbejoro fun awon olujejo ni tie, Ogbeni Alaba Awoseemo ro ile ejo lati faaye beeli sile fawon olujejo pelu alaye pe won ko nii salo fun igbejo nitori pe won setan lati fi awon oniduro to looko sile.
Awoseemo fi kun oro re pe iya to bi omo ti won fipa ba lopo gan an ko nife si ejo naa mo.
Sugbon agbejoro funleese olopa lodi si arowa agbejoro olujejo, o ni omobinrin naa ko gbadun rara latojo ti won ti fipa ba a lopo.
Ninu idajo re, adajo majistreeti naa, Risikat Olayemi ni ohun ti agbejoro funleese olopa so nipa olupejo ko lese nile rara nitori pe o ti gbon lati mo ohun to fe funraare.
O waa pase pe ki omobinrin naa farahan nile ejo lojo kejidinlogbon osu kejila to sun igbejo si ati pe ki agbejoro fawon olujejo loo ko leta fun gbigba beeli won lona to ba ofin mu.
O ni ki won loo fi awon meteeta pamo sogba ewon titi di ojo kejidinlogbon osu kejila ti won yoo soro lorii beeli won.

No comments:

Post a Comment