Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ni ki gbogbo awon omo orileede yii fokanbale nitori pe gbogbo wahala to n mi orileede yii logbologbo bayii ko nii pe dohun igbagbe.
Bee lo so pe gbogbo awon omo Yoruba ni won gbodo dide lati wa nnkan se si oro ede abinibi wa to dabi eni pe o ti n di nnkan igbagbe lo bayii, paapa laarin awon odo ti won je ogo jo ola ile Yoruba.
Ooni soro yii ninu ilee re to wa ni Parakin nilu Ileefe lasiko ti awon alase ileese Nigerian Breweries eleyii ti adarii won lekun Ibadan, Ogbeni Joseph Bodunrin ko sodi sabewo ikinni ku oriire sii.
Oba Ogunwusi ni se ni kawon eeyan orileede yii maa farada gbogbo ilakoja ti orileede yii n dojuko lowolowo nitori pe ayo ni yoo jasi lopin re.
Gege bi Oba Ogunwusi se wi, kii se igba akoko niyii ti orileede yii yoo maa koju ipenija olokanojokan sugbon ayo lo n jasi nigbeyin niwon igba ti ifowosowopo ba ti wa.
Saaju ninu oro re, Ogbeni Bodunrin ni ileese naa waa sabewo si kabiesi lati fi atileyin won han si gbogbo awon odun isembaye to wa nilu Ileefe ati paapa, imuraa won fun odun Olojo to n bo lona.
Bodunrin salaye pe ileese Nigerian Breweries setan lati maa ko ipa to jou ninuu gbogbo awon nnkan o ba ti je mo isembaye peluu bi Ileefe se je orirun gbogbo omo Yoruba.
Oba Ogunwusi waa gbosuba fun ileese naa, o si fi asiko naa so fun won nipa ile eko ere idaraya eleyii ti yoo bere nilu Ileefe ki odun yii too pari, nibi to ti nireti pe ileese naa yoo je okan lara awon agbateru re.
Ooni waa ro gbogbo awon ileese nlanla to ku lati sawokose Nigerian Brewries nipa sise nnkan fawon araalu lojuna ati mu ise ati osi kuro lorileede yii.
Tuesday, 8 December 2015
Ooni Ogunwusi so asotele pe Naijiria yoo bori isoro re laipe
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment