Aare egbe awon akekojade ile eko giga gbogbonise tilu Iree, Oloye (Arabinrin) Mobola Odebode ti so pe awon igbese ti Gomina Aregbesola n gbe lori awon ile eko giga mereerin to je tijoba ipinle Osun, iyen ile eko gbogbonise ilu Iree, ti imo ero to wa nilu Esa Oke, ti ile eko olukoni agba to wa nilu Ilesa ati tilu Ila Orangun je eyi ti yoo mu ifaseyin ba eto eko nipinle Osun.
Mobola soro yii loruko awon aare ile eko giga to ku, o ni iyalenu lo je fawon pe ijoba ipinle Osun ti kowe sajo JAMB lati yo oruko awon ile eko mereerin kuro ninu silaboosi, eleyii to tumo si pe ko si omo kankan ti yoo lanfaani lati wo awon ile eko naa fun odidi odun meji.

No comments:
Post a Comment