IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 2 December 2015

Igbeyawo olodun merindinlogun tuka n'Ileefe nitorii .......

Iyaale ile kan nilu Ileefe, Olatoyosi Adeniji ti ro kootu koko-koko nilu naa lati tu igbeyawo aarin oun atoko oun ka.
Esun ti obinrin olomo meta naa fi kan oko re, Adewumi ni pe kii toju oun atawn omo oun, ija ni ni gbogbo igba, ati pe lati odun 2012 lo ti pa oun ti laibikita lorii bi oun atawon omo se n gbele aye.
Olatoyosi ni oko oun kii ba oun fowosowopo nigbakuugba toun ba gbero nnkan rere fundile awon lati odun 2004 tawon ti fera.
O fi kun oro re pe omo meta; Adekanmi to je omo odun mewa, Adedeji to je omo odun mejo ati Adesina toun je omo odun merin ataabo bayii loun ti bi fun Adewumi sugbon to je pe adagbe-adafa ni bukata won foun lati odun 2012 toko oun ti pa oun ti.
Bo tile je pe omobinrin yii ti loko miin lodun to koja, o ni o pon dandan fon lati wa sile ejo ki won lee tu igbeyawo naa ka nilaana ofin ibile.
Nnu awijare ti okooyawo, o ni oun paapa faramo igbese titu igbeyawo naa ka sugbon ko si ooto ninu gbogbo ejo tiyawo oun ro mo oun lese.
O ni dida lo da ti omo degbe oun, nitori pe Olatoyosi niyawo keedogun toun yoo fe latari isoro airomobi toun ni. O fi kun oro re pe nigbakuugba toun ba ti fee ba iyawo oun sere ife bayii lo maa gba egberun  lona mewa naira lowo oun ati pe toun ba ti nii lokan pe kawon bimo le omo bayii, oun gbodo koko ko egberu lona aadota naira kale ko too gba foun.
O ni sibe, gbogbo eleyii ko te iyawo oun lorun ri, afigba to loo fi ojukokoro fe dokita tidile oun maa n lo, nitori idi eyi, oun gan an ti setan fun ikosile.
Ninu idajo re, aare kootu naa, Alhaji Ganiyu Awoyera ni leyin tawon ti sakiyesi pe ko si ife mo laarin awon mejeeji, won tu igbeyawo naa ka laida owo ori pada.
Awoyera ni ki awon omo meteeta wa lakata iyaa won ati pe ki baba won maa san egberun lona ogbon naira losoosu funtoju awon omo naa.
O tun pase pe ileewosan ijoba niyawo gbodo maa gbe awon omo naa lo funtoju nigbakuugba ti won ba saisan ati pe baba won gbodo maa sanwo ileewe won ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment