IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 1 December 2015

L'Osogbo, Azeez ji mansinni omi, ladajo ba ju sewon odun meta

Omokunrin eni ogun odun kan, Azeez Toheed ti won fesun kan pe o ji mansiini ifami, iyen pumping machine mefa to je tijoba apapo ladajo ti ran lewon odun meta bayii.
Ojo kerindinlogun osu kokanla odun yii lowo ajo sifu difensi te Azeez ni Federal Housing Estate to wa ni Ogo-Oluwa area, Osogbo nigba to fe maa salo leyin to ji awon mansinni ohun tan.
Leyin ti won mu un, to si jewo pe loooto loun ji awon mansinni to je ti ajo Federal Housing Authority, ni won gbe ejo re lo sile ejo giga tijoba apapo to wa nilu Osogbo.
Esun meji otooto ni won fi kan Azeez. Akooko ni pe o mo on mo ba nnkan ijoba je ati pe o ji mansinni omi ti owo re je egberun lona ogorun o le meji naira, eleyii ti won ni o lodi si ofin ijoba apapo orileede Naijiria ti odun 2004.
Nigba ti akowe kootu ka awon esun mejeeji ti won fi kan Azeez, eni ti ko ni agbejoro kankan to n gbenuso fun un, leti, o ni oun jebi awon esun naa sugbon ki adajo dakun siju aanu wo oun, ki won mase je ki iya ese oun poju agbara lo.
Nigba to n gbe idajo re kale, Onidajo Babs Kuewumi pase pe ki Azeez faso penpe roko oba fun odun meji pelu ise asekara fun esun akooko.
O ni odun kan pere ni yoo lo lewon pelu ise asekara lori esun keji ti won fi kan an, sugbon se ni ko lo odun meteeta naa leralera.

No comments:

Post a Comment