IROYIN YAJOYAJO

Monday, 7 December 2015

Ile ejo kotemilorun so pe Buruji Kashamu lo jawe olubori lekun Ila-Oorun Ogun


Ile ejo kotemilorun, iyen Court of Appeal, eleyii to fi ilu Ibadan sebujoko ti so pe ko si ariyanjiyan kankan rara lorii bi ajo eleto idibo ile wa se kede Seneto Buruji Kashamu gege bii eni to jawe olubori ninu idibo sile igbimo asofin agba to waye lekun Ila-Oorun ipinle Ogun losu kerin odun yii.
Ile ejo to n ri si esun to suyo leyin idibo, Elections Petitions Tribunal ti koko so ninu osu kewa odun yii pe oun fagile ibo to gbe Buruji wole nibe, o si pase pe ki won satundi ibo si woodu mokandinlaadofa.
Idi niyii ti Buruji fi fori le ile ejoo kotemilorun lati fi ejoo Ogbeni Dapo Abiodun to pe e lejo latinu egbe oselu APC ati ajo eleto idibo sun.
Ajo to n ri si eto idajo lorileede yii ti koko tu igbimo ile ejoo kotemilorun to bere igbejo naa ka lori esun pe won ni Buruji fun won lowo ibobe sugbon igbimo miin ti won gbe kale bayi ni won kede Buruji gege bii eni to jawe olubori.

No comments:

Post a Comment