IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 16 December 2015

Lori esun dida ileewe ru; awon akeko mefa foju bale ejo

Awon odomokunrin mefa ti won je akeko ileewe girama St Marks Anglican High School ati Adenle Middle School lagbegbe Testing Ground nilu Osogbo ni won farahan niwaju adajo majistreeti kan lopin ose to koja lori esun meji otooto.
Awon akeko ohun yi gbogbo won je omo odun mejidinlogun ni won fesun kan pe won gbmopo lati da wahala sile nileewe won lojo keje osu kejila ti awa yii, bee ni won tun ni won huwa to lee da omi

alaafia agbegbe naa ru nipa lile awon oluko won kaakiri pelu ibon ati ada.
Awon akeko ohun ni Adewunmi Olusegun, Ajibola Toheeb, Ganiyu Sodiq, Adegbite Femi, Atoyebi Nurudeen ati Adepoju Yusuf.
Gege bi agbejoro funleese olopa lori oro naa, Taiwo Adegoke se salaye funle ejo, se lawon akeko naa ko igi, okuta, ada ati ibon loo ka awon oluko won monuu ileewe lojo naa, ti won si da hilahilo kale.
Adegoke ni iwa tawon omo naa hu lodi si ofin, o si ni ijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun ti odun 2003.
Nigba ti akowe kootu ka awon esun mejeeji ti won fi kan won si won leti, won ni awon ko jebi awon esun naa.
Bakan naa ni agbejoro kan to je afenifere (amicus curiae) ro ile ejo lati faaye beeli sile fawon akeko naa, o ni won ko tii jebi awon esun mejeeji ti awon olopa fi kan won ayafi igba ti ile ejo ba da won lebi.
Nigba to n gbe idajo re kale, adajo majistreeti naa, Olajumoke Olowolagba faaye beeli sile fun okookan awon akeko naa pelu egberun lona igba naira ati oniduro meji-meji ni iye kannaa.
Bakan naa lo ni okan lara awon oniduro naa gbodo le fi iwe eri owo ori re bo se n san an deede han.
O waa sun igbejo siwaju di ojo keedogun osu keji odun to n bo.


2 comments: