IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 5 January 2016

Wahala n bo l'Osogbo, awon olorisa atawon musulumi fee gbena woju araa won


Awon olubo Orisa-Oko nilu Osogbo ti kilo pe ki awon musulumi ilu naa ti won n gbero lati wo ojubo orisa awon nitori atunko mosalasi nla to wa nitosi ibe sora gidigidi, ki won mase dawole ohun to le da omi alaafia ilu naa ru.
Pa Jimoh Iyanda to je agba molebi awon olusin Orisa-Oko nilu Osogbo so pe ogun ibi awon ni ojubo naa ati pe awon ko lee fi ba enikeni sere rara.
Won ni ko si ooto ninu oro tawon musulumi kan n so kaakiri pe awon molebi awon kan ti gba owo lati yonda ojubo naa ati pr ko si iye tenikeni le gbe sile fawon to le je kawon ta ogun ibi awon.
O ni awon alase mosalasi to wa ni Oja Oba naa gbodo tun ero won pa lorii fife ti won fee fe mosalasi naa eleyii ti won ni yoo sakoba fun ojubo orisa awon.
Bakan naa ni won ro Ataoja tilu Osogbo, Oba Jimoh Olanipekun lati da si oro naa nitori ko nii dara ki enikeni gbe igbese ti yoo da omi alaafia ilu Osogbo ati tipinle Osun lapapo ru.
Awon Olorisa Oko salaye siwaju sii pe t awon musulumi ilu Osogbo ba mo pe awon fee fe mosalasi naa loju, ki won lo sibomiin ti ile won wa; yala ni Oke Baale tabi oju ona ojubo Osun Osogbo.
Won ni awon ko nii fojuure wo enikeni bo tile wu ko lagbara to, to ba pinnu lati fowokan ibi tawon ti n sin orisa awon nitori pe iwe ofin orileede yii gan an paapa faaye gba gbogbo eniyan lati sin esin to ba wu u.

No comments:

Post a Comment