IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 2 February 2016

Fayose sabewo si Aregbesola; o ni bi iran Yoruba ko se nii di atemere lo je oun logun

Gomina ipinle Ekiti, Dokita Ayodele Fayose ti ke si gbogbo awon lookolooko ninu iran Yoruba, paapa awon gomina ti won je tipinle Yoruba lati mase fowoleran ki won si maa woran ki iya ati abuku maa ba awon asaaju iran naa.
Fayose, eni to sabewo manigbagbe si gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola nile ijoba nilu Osogbo lose to koja woye pe awon arifin kan ti fee maa ta le awn asaaju iran Yoruba, eleyii to ni o ye ki tolori telemu dide lati tako nitori pe mokan-mokan loye agba yoo kan gbogbo eeyan.
O ni ko si ooto kankan ninu eso to n lo kaakiri pe se loun fee waa be Gomina Aregbesola si Buhari ko ma baa fungun mo oun, sugbon oun sabewo si gomina ohun gege bii eni ti oro ojoowaju iran Yoruba je logun.
Gege bo se wi, "Gbogbo wa la leto lati so ohunkohun to ba ru wa loju sita, ko si si eni to le pohun mo agogo mi lenu laelae, sugbon mo wa lati je ka forikori lori oroo bi iran Yoruba yoo se wa nisokan ati irepo ninu ohun gbogbo ti a ba n se.
"Digbi ni mo wa ninu egbe oselu PDP, n ko lee kuro nibe nitori mo nigbagbo pe ti ko ba si egbe oselu alatako, se lawon egbe to ba wa nijoba yoo maa jayee familete ki n tuto, ti won ko si nii mo inira to ba n de ba awon araalu.
"Eko nla ni abewo ti Ooni ti ilu Ileefe, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja Keji se si Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi laipe yii ko gbogbo wa, o si paroko si wa pe asiko ti to fun ife ati irepo laarin iran Yoruba nitori pe airinpo ejo wa ti fee maa fi iya je wa bayii.
"Nitori idi eyi lemi naa se pinnu pe a gbodo gbe igbese lati wa ojutu si iyapa to n fojoojumo gbile laarin iran Yoruba, igba akooko si niyii ti maa sabewo si ipinle to je ti egbe oselu APC, a gbodo gbagbe nipa oselu tabi esin bayii, iran Yoruba tobi ju gbogbo wa lo, ti a ba ko lati wa irepo iran Yoruba, awon aromodomo wa yoo bi wa leere".
Ninu oro tire, Gomina Aregbesola ni iyalenu ni abewo Gomina Fayose je fun oun ati pe ipenija si ni abewo naa je pelu nitori pe ko faaye gba ipo agbara lati je ko gbagbe iran re.
Aregbesola waa seleri fun Fayose pe gboingboin loun wa leyin re lorii gbogbo igbese to ba ro pe awon le gbe lati wa ojutu si iyapa ati ainisokan laarin iran Yoruba.
Lara won ti won ba Fayose koworin lo sibe ni akowe agba funjoba ipinle Ekiti, Dokita Dupe Alade, olori osise loofiisi gomina, Barista Dipo Anisulowo, abenugan ile igbimo asofin, awon komisanna, awon alaga ijoba ibile, alaga egbe oselu PDP nipinle Ekiti, Oloye Idowu Faleye ati bee bee lo.

No comments:

Post a Comment