Baba agbalagba eni aadorin odun o le eyokan, Adewale Muritala ti foju bale ejo majistreeti kan nilu Osogbo lori esun pe o lu ijo Ridiimu ni jibiti obitibiti owo.
Ile ijo la gbo pe baba agba yii seleri fun Pasito ijo ridiimu naa, Pasiyo Alade Samuel lati ba won ra latinu osu keji odun un 2012 sugbon ti oro ohun pada ja si jibiti.
Gege bi agbenuso funleese olopa lori oro naa, Taiwo Adegoke se so nipe ejo, milioonu kan ati egberun lona agbefa naira ni bab yii gba lowoo pasito sugbon ti won ko ri owo, bee ni won ko ri ile latigba naa.
Esun meji otoito to nii se pelu lilu jibiti ati ole jija ni won fi kan Baba Muritala, eleyii ti won lo se lagbegbe Temidire Estate nilu Osogbo.
Adegoke ni ile to je pe enikan lo ti sanwo e ni baba yii tun fi han awon ara ijo Ridiimu ati pe asiri tu nigba teni to ti koko sanwo ile yoju sibe.
O ni iwa ti baba ohun hu lodi sibofin iwa odaran ti odun 2003 tipinle Osun nlo ati pe o nijiya bakan naa.
Leyin ti olujejo so pe oun ko jebi awon esun ti won fi kan an ni agbejoro re, Arabinrin Oketade Olufunke ro ile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo peu ileri pe ko nii sa fun igbejo.
Ninu idajo re, adajo majistreeti naa, Arabinrin Halimatu Bashiru faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro meji ni iye kannaa.
O ni awon oniduro naa gbodo fi eri owo ori sisan won sile, ki won si maa gbe lagbegbe ile ejo.
Thursday, 27 October 2016
L'Osogbo, baba arugbo lu ijo Ridiimu ni jibiti owo; lo ba foju bale ejo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment