IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 23 November 2016

Awon adigunjale ko leta sawon ara Osogbo, won lawon n bo waa gba nnkan odun

Koju ma ribi, gbogbo ara loogun re loro da fawon eeyan agbegbe Kelebe nilu Osogbo bayii pelu iwe nla ti won ri gba latowo awon adigunjale ti won pe oruko araa won ni Fejesofo Fraternity.
Lati bii ose meji la gbo pe awon apa kan lagbegbe Kelebe ti ri iwe tiwon gba sugbon ti won se oro naa ni arunmora, nigba to waa di wipe awon apa ibomiin tun n gba a leralera ni won figbe ta.
Ile awon alaga agboole kookan ninuu Kelebe la gbo pe won n le iwe naa mo, ohun ti awon iko Fejesofo si n so ninuu leta won ni pe awon ti awon ni oru oganjo fee ba won lalejo.
Won ni awon ko fe nnkan meji ju owo atawon dukia to lee di owo kiakia lo ati pe ki enikeni to ba ro pe oun ni ayeta tabi ajaro mo pe digbi lawon wa bii ibon.
Ninu leta naa lawon iko adigunjale ohun ti salaye pe iko eleni marun lawon, oruko awon maraarun si ni Kogberegbe, mujemuje, dunbu e, akeeke ati salaake.
Won ni ko si wahala kankan bo ti wu ko mo fun enikeni to ba fowosowopo pelu awon laisi awawi sugbon ewu wa loko longe fun enikeni to ba n ba awon so itan arowo tawon ba wole.
Bakan naa ni won daruko die lara awon adugbo ti won ti sabewo si fun idaniloju enikeni to ba ro pe ihale lasan ni leta ti won ko.
Eleyii lo faa tawon eeyan agbegbe naa fi n dogbon mu aso won ni meji meta, ti won si n sa kuro nile ko too di pe awon 'lanloodu agba' yii yoo de ba won lalejo.
Ninu oro tire, agbenuso fawon eeyan agbegbe Kelebe, Ogbeni Hakeem Bolarinwa rawo ebe sawon olopa lati mase foro leta naa sawada rara ati pe o kuro leyii ti won le foro yepere mu rara. O ni ki won jowo seto aabo fun emi ati dukia awon eeyan agbegbe naa.
Sugbon komisanna ileese olopa l'Osun, Fimihan Adeoye nipase alukoro, Folasade Odoro ni ko sewu rara. O ni awon yoo sewadi leta naa lati gbe igbese to ye lori e.

No comments:

Post a Comment