IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 22 August 2017

L'Osogbo, Timileyin atawon oree re fibon gba moto lowoo Taiwo


Ko too di pe igbejo yoo bere lori esun ole jija ti won fi kan omokunrin kan atawon oree re meta, odidi osu meta ni won yoo koko fi jiya logba ewon ilu Ilesa.
A gbo pe tibontibon lawon afurasi ohun; Awe Timileyin, Ojo Abayomi, Rotimi Adedeji ati Segun Adelabi fi ja moto Toyota Camry gba lowoo Adekanmi Taiwo Uthman lagbegbe Corpers' Lodge ni Dada Estate, Osogbo.
Apapo owo nnkan ti won ji lowoo Taiwo lojo naa je milioonu kan le igba naira.
Leyin atotonu Inspekito Olusegun Elisha ni adajo Majistreeti naa, Olubukola Awodele pase pe kawon olujejo loo se faaji logba ewon ilu Ilesa titi di ojo kerinlelogun osu kokanla odun yii tigbejo yoo bere lori oro won.

No comments:

Post a Comment