Egbe kan ti kii se tijoba, Asiwaju Grassroots Foundation (AGF) ti kilo fawon eeyan ipinle Osun lati yera fun awon oloselu ti won n kaakiri bayii lati gba ojulowo lowoo won, ki won gbe ayederu le won lowo.
Ninu oro ikini ku oriire ti egbe naa fi sita fun ti ayeye odun kerindinlogbon ti won da ipinle Osun sile lo ti so pe oniruuru ise itesiwaju ti Gomina Aregbesola ti se l'Osun koja eyi ti enikan yoo kan dede waa fi buredi ko awon araalu lomi obe je.
Gege bi alakoso egbe naa, Komreedi Tijani Sikiru lo ti so pe gbogbo awon ti won ti dari ipinle Osun latigba idasile ni won se takuntakun sugbon akanse ni ti Gomina Aregbesola je laarin won.
O ni iyalenu lo je pe awon oloselu kan ti won ko ni Ife araalu lokan bikose ki won ba awon nnkan rere ti Aregbesola ti se je ti n lo kaakiri bayii lati toro ibo fun odun to n bo.
O waa ro awon araalu lati tubo maa fowosowopo pelu Gomina Aregbesola ki awon nnkan meremere le maa tesiwaju sii l'Osun.
Monday, 28 August 2017
E fura o! Awon abanilayoje ti kun ipinle Osun bayii - AGF
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment