IROYIN YAJOYAJO

Monday, 28 August 2017

Asofin ipinle Osun pariwo; ijoba amunisin nijoba Aregbesola o

Adari awon asofin to kere ju nile igbimo asofin ipinle Osun, Onorebu Safiriyu Akinwale Akinwole ti pariwo pe nse ni Gomina Aregbesola n se awon bii eru nile igbimo asofin.
Lasiko to n kopa lori eto orii redio Rave FM lo ti so pe gomina ko fun awon lanfaani lati sise kankan fawon ti won yan awon.
Akinwole ni looto ni abenugan ile, Najeem Salam je okunrin takuntakun sugbon awon kan tun wa ninu egbe APC ti won maa n ka a lowo ko, ti kii fii raaye se oun to to.
O fi kun oro re pe se ni Aregbesola ko awon ni papamora nile asofin, to si je pe ohun kansoso to fe ni kawon asofin maa dobale fun un ko too fun won lowo osu ati ajemonu.
Ara eleyii lo so pe o fa a ti wahala fi n sele laarin awon osisefeynti atijoba Osun lojoojumo nitori agidi inu ni gomina fi n sejoba.

No comments:

Post a Comment