Abileko eni odun metadinlogoji lowo ileese olopa ipinle Oyo ti te bayii lori esun pe o ni kawon kan ji oun gbe, ki won gba owo lowo oko oun nitori oun fee lo silu oyinbo.
Bukola Ogun lo so pe lati le deruba oko oun loun se ni kawon kan ji oun gbe nirole ojo kerin osu keje odun yii nitori oun mo pe kia ti won ba tu oun sile loko oun yoo seto irinajo ilu oyinbo foun.
Bukola, eni toun ati oko re ti feraa won lati nnkan odun mefa seyin, ti omo meji si ti wa ninu igbeyawo naa lo padi apo po peluu Kayode Adepoju to je molebii re lati huwa naa, ki won si beere milioonu mewa naira lowo oko re.
Laarin ojo meteeta ti oko fi n wa a kaakiri, ileetura kan lagbegbe Imolefalaafia nilu Ibadan la gbo pe o ti n se faaji.
Leyin iwadi awon olopa lasiri tu pe Bukola gan an lo wa nidi iroyin ijinigbe araa re.
Monday, 28 August 2017
Home
/
Unlabelled
/
Nitorii Amerika, Bukola ni ki won ji oun gbe; milioonu mewa naira ni won beere lowo oko e
Nitorii Amerika, Bukola ni ki won ji oun gbe; milioonu mewa naira ni won beere lowo oko e
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment