IROYIN YAJOYAJO

Friday, 25 August 2017

Awa ko la wa nidi ailera re o, koda, tosantoru la fi n sadura fun o - Makarfi

Alaga apapo fun egbe oselu PDP lorileede yii, Seneto Ahmed Makarfi ti so pe balau ni inu awon omo egbe oselu PDP mo lori oro ailera to n se Aare Mohammed Buhari.
Lasiko ti Aare Buhari n sepade pelu awon asoju egbe oselu APC ati PDP nilu Abuja ni Makarfi ti so pe bi awon tile je egbe oselu alatako, sibe iyen ko so pe kawon ro iku ro Aare.
Makarfi ni gbogbo anfaani tawon ni lawon fi n gbadura kikankikan fun imubosipo Aare, bee ni Olorun si ti gbo adura awon pelu bi Aare Buhari se pada wale pelu ilera pipe.

No comments:

Post a Comment