IROYIN YAJOYAJO

Friday, 25 August 2017

Iranse asetaani kan re o! Aafa Sule lu Fisoye ni jibiti milioonu meta naira

Afi bii maalu ti moto ja sile ni okunrin kan to n pe araa re ni Aafa nilu Iwo nipinle Osun se n wo nile ejoo majistreeti ilu Osogbo lasiko to n wi tenu e lori esun jibiti lilu ti won fi kan an.
Se ni Dada Sulaiman Jimoh eni odun marundinlogbon so pe oun yoo ba okunrin kan, Adeyemi Fisoye se aajo ti aisan kan to n se e yoo fi lo patapata. Sugbon leyin to gba milioonu meta naira lowo e tan lasiri too tu pe abamoda ni gbogbo e.
Abaa Lamuyan lagbegbe Iwo nisele naa ti sele. Amo sa, onidajo majistreeti naa, Habitat Basiru pase pe ki won loo fi Aafa Sule pamo sogba ewon Ilesa titi dipari osu kejo tigbejo re yoo bere nile ejo majistreeti ilu Iwo.

No comments:

Post a Comment