IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 24 August 2017

Iku oro o! Olopa yinbon pa oga e, loun naa ba be sinuu kanga

Kayeefi loro naa si n je fun gbogbo awon tisele naa sojuu won lago olopa Kajola Divisional police station to wa nipinle Ondo lasiko ti won dede gburo ibon, to si je pe oku oga olopa kan ni won n wo nile.
Oro owo kan to je egberun lona aadojo naira (#150,000) la gbo pe o da wahala sile laarin Inspekito Abraham Arowogun ati oga e DCO Timothy Aruehi, ka too wi, ka too fo, Abraham ti fa ibon yo, o si fi pa ogaa re.
Ori iyen lawon olopa egbe re wa ti won fi gbo pe Abraham ti be sinuu kanga kan to wa leyin ago olopa ohun.
Alukoro ileese olopa ipinle Ondo, Femi Joseph fidi isele naa mule, o si so pe iwadi ti bere lori e.

No comments:

Post a Comment