Owo ileese olopa ipinle Osun ti te omokunrin eni ogun odun, Dada Adebayo lori esun pe o ji komputa kan ati foonu meji to je ti Ogbeni Olusola Adeyeye.
Ojo keji osu keji odun yii la gbo pe Dada huwa naa lagbegbe Saka Raji ni kobongbogboe nilu Osogbo ni nnkan aago kan aabo osan.
Owo to le ni egberun lona igba naira ni apapo nnkan ti olujejo ji ohun. Idi si niyii ti adajo majistreeti, Sodamade Fatimah fi faaye beeli sile fun un pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro meji ni iye kanna.
O waa sun igbejo siwaju di ojo kokanla osu kesan odun yii.
Friday, 25 August 2017
L'Osogbo, Dada ji konputa Sola, lo ba foju bale ejo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment