IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 23 August 2017

Ikunle Abiyamo o! Omo Yahoo fi moto ran olopa meji sorun loju ona Osogbo si Ilesa

Beeyan jori ahun, to ba de orita AKAD loju ona Osogbo si Ilesa, poroporo lomi yoo maa jabo loju e nigba to ba n wo awon olopa meji ti omokunrin kan fi moto pa yannayanna sibe.
Omo Yahoo laheso ta n gbo kaakiri pe Olumuyiwa Emmanuel to wa moto Toyota Camry naa je bo tile je pe awon olopa ni awon ko tii mo.
Se la gbo pe Olumuyiwa n sa fawon olopa pelu moto re to ni nomba MUS 313 ET to fi loo te awon olopa mejeeji ti won n ye iwe oko wo nikorita naa.
Emmanuel omo odun metalelogun ohun ti wa lakolo awon olopa bayii.

No comments:

Post a Comment